Nọ́mbà àkọ́kọ́
From Wikipedia
Ninu Ìmọ̀ Ìṣirò nọ́mbà àkọ́kọ́ (prime numbers) ni a mo si awon nomba adaba (natural numbers) ti won ni nomba adaba meji pere ti a le fi pin won dogba, eyun ni nomba 1 ati nomba akoko fun ra ara re. Awon nomba akoko po to be to fi je pe won ko lopin gege bi Efklidi se fihan ni odun 300 K.J (kia to bi Jesu, K.J). Nomba odo 0 ati ọ̀kan 1 ki se nomba akoko.
Bi awon nomba akoko se tele ara won ni yi : 2, 3, 5, 7, 11, 13, 17, 19, 23, 29, 31, 37, 41, 43, 47, 53, 59, 61, 67, 71, 73, 79, 83, 89, 97, 101, 103, 107, 109, and 113
Nomba 2 nikan ni o je nọ́mbà tódọ́gba (even number) larin won. Awon to ku je nọ́mbà tósẹ́kù (odd numbers).
[edit] Nomba Akoko gege bi baba awon nomba adaba
Ipilese Agbagbo Isesiro la kale pe gbogbo nọ́mbà odidi (integers) apa otun ti won tobi ju 1 lo se ko sile gege bi isodipupo nomba akoko kan tabi jubelo ni ona kan pato. Fun apere a le ko:
[edit] Gbogbo Awon Nomba Akoko
Awon nomba akoko ko ni ye. Eyi ti je fifihan lopolopo ona. Eni akoko to koko fi eyi han ni Efklidi. Bi o se fi han ni yi:
- E je ki a so pe awon nomba akoko to l'opin (finite) kan wa. E je ki a pe awon nomba wonyi ni m. Se isodipupo gbogbo m, ki o si se aropo re pelu okan (nomba Efklidi). Nomba esi ti ri ko se pin pelu ikojopo number akoko kankan t'olopin, nitoripe bi a ba se pin to okan yio seku, be sini okan ko se pin pelu nomba akoko. Nipa bayi, tabi ki o je nomba akoko fun ra ara re tabi ki o se pin pelu nomba akoko miran ti ko si ninu ikojopo to l'opin. Botiwulekaje, a gbudo ni nomba akoko ti yio je m + 1.