Nọ́mbà tódọ́gba
From Wikipedia
Ninu Imo Isiro, gbogbo nọ́mbà odidi le je nomba todogba (even number) tabi nomba toseku (odd number) lona yi: ti o ba je odidi nomba ni opolopo meji, nomba na je nomba todogba bibeko yio je nomba toseku. Fun apere 4, 0, 8, 16 je nomba todogba bee si ni 1, 3, 7, 9, 11 je nomba toseku.
Akojopo awon nomba todogba se ko bayi:
- Todogba = 2Z = {..., −6, −4, −2, 0, 2, 4, 6, ...}.
Akojopo awon nomba toseku se ko bayi:
- Toseku = 2Z + 1 = {..., −5, −3, −1, 1, 3, 5, ...}.
Contents |
[edit] Isirosise pelu awon nomba todogba ati nomba toseku
[edit] Aropo ati Iyokuro
- todogba ± todogba = todogba
- todogba ± toseku = toseku
- toseku ± toseku = todogba
[edit] Isodipupo
todogba * todogba = todogba
todagba * toseku = todogba
toseku * toseku = toseku
[edit] Isepinpin
Ti a ba sepinpin odidi nomba ki se dandan pe yio fun wa ni nomba odidi pada. Fun apere ti a ba sepinpin 1 pelu 4, esi re yio je 1/4 ti ki se nomba todogba tabi nomba toseku nitoripe awon nọ́mbà odidi nikan ni won le todogba tabi toseku. Sugbon ti ipin ba je odidi nomba, yio je todogba ti afi ti nomba ti a pin (dividend) ni opolopo iye (factor) meji ju nomba ti a fi pin (divisor) lo