Amharic
From Wikipedia
Amharic
Amuhariiki
Amariiki
Èdè Sèmítíìkì (Semitic) kan ni eléyìí tí nnkan bú mílíònu márùndínlógún ń so gégé bí èdè àkókó ní Ethopia (ìtópíà). Níbè, wón ń lò ó gégé bí tí ìjoba ń mú lò. Àwon bú mílíònù márùn-ún ni ó ń so èdè yìí ní agbègbè Ethiopia nígbà tí àwon òpòlopò mílíònù mìíràn ń so èdè yìí gégé bí èdè kejì àkókúntenu ní Ethiopia àti Sudan (Sùdáànù). Láti nnkan bíi séńtúrì kerìnlá (14th Century) ni èdè yìí ti ní àkosílè. Àkotó Amharic ni wón fi ko ó sílè. Àkotó yìí ní Kóńsónántì métàlélógbòn òkòòkan won sì ní èdà méjeméje. Èdà kóńsónántì tí ènìyàn yóò mú lò dúró lóró fáwèlì tí kóńsónántì náà yóò bá je yo. Àbá ti ń wáyé nípa pé kí àtúnse wà fún àkotó yìí. Àwon kan sì ti kóra won jo fún ìpolongo láti so èdè yìí di àjùmòlò (Standardisc).