Ajoriiwin
From Wikipedia
Ajoriiwin
[edit] ORÍKÌ AJOJRIIWIN
Omo ibú owó,
Omo orilè bo yìgì
Omo aninure tó dára
Omo inú u re ò bòsumàrè
Omo Aláo téè dabù èrin
Wón á láró laáfúsá fé a re,
À tó bòkùn ye e.
Abisòkòtò bí ìgbókin mefà nilé Aláró,
Òpó ilé kìrì mole
Esin oba kó máa móko je
Eyin le fòfè móba loyòó
Lení kóba ó gbó kóya ó tó,
Ìlú ò jísé omo a jísé e re fóba.
Èyin le fòfè móba loyòó
Téni kóba ó gbó, kóya ó tó
O ò fóhùn ògìì.
Baba à mi, ó sì fin nu se o o
Àjàlá ògbó, baba à mi, ó sì fún mi se
Omo Arówá lá mole,
Baba a mi ó sì fún mi se
Omo Arówó òkè yá ìwòfà,
Omo òletù lagbàlá,
Abéyé e sisé oko, baba à mi, ó sì fún se
Omo íwù ló wù ìjòkùn,
Èyí té e dúdùú èlú
Omo Aláró lá a fun láso, ó sì jòkìn ye
Omo bàbá Epééle,
Baba à mi, ó sì fún mi se
Ìlu, ó sì dá a o ,
Ìlú s sì tòrò
Yóó tòrò títí bí omi a faro pon,
Baba à mi, ó sì fún mi se
Àjàlá òkò, Baba à mi, ó dúró léyìn mi
Omo Epééle, omo ìwù ló wù jòkùn tée dúdu èlú
Omo Aláró láa rún laso re, ó kù jòkùn re
Ò ò gbó bó ti n kì wón
O kìjàlá owó tán.
Àpóo lórigi, n lèrún pekun óná o,
Wón lé lááyinba ti I jásé omo
Boò pekun poyáaá
Olúuwa à mi moo pekún pa yinniyinni
À ó máa darijo pèlé ò rín.
Emi le ní kómo eranko ó mó ri mú je
Omo ò ji lóru tìnrin, tinrin rin
Oluùwa à mi, mo be ròrò loòkùn
Ma wulé, ó wùjòkùn-un
Báyìí kée dúdú èlú
Omo on a múlé tegbó
Oníkèé gbàmí baàsàlè
Omo on kan dúdú gbó jònù
À á se é bókan oya, kan ni, Àkanlú òkín
Omo Èjìgbà ìlèkè
Omo òkan ti i féé sowó aso funfun ní lala ní lala.
E è póluuwa mí oo,
Omo a bá à gbàjà,
Àpó o lóri igi èrin pèkún enu o o.
O ò gbó bó ti wi yìí o, Adénìólá
Ake o, èdú, Adé ni, Baba dada
Ojúolápe Ajojo, a boju were
Omo ò fi bere bóyin wi
Baba à mi lomo o fi béefe bóyin jà
Omo Baba ó jà, bábá á,
O nílùú kú tán, ó jalé tàjá book
Olúáyé, oya a kiri aye oba ó roku
Omo a ì bóba ja ni mèfe
Baba à mí, oya méta ìjà ò fi èn
Oníbùdó yeja,
O n yiki, bó ti jókòó è jéjé éjé
Omo amuni lóòle, ò mohun ti i se ni
O ò gbó bó ti n kì won
Omo a gún léyinjú ú
Máa double dú tewutewu
Èwù ògún lójú elégàn Baba òdétólá
Agogo ò, bi eni ti n tení se
O ò gbo bó ti n pàjàó ó o
Ajàó ògun omo òkún yéye
Àkànbí èdú, omo òjéléye
Pópóolá omo ara táako
Omo a yí gbìgbi yi gbigbí lóko
Omo a fògún yi gbìrìgbìrì lajà
Omo a fògún yi gbìrìgbìrì lajà
Omo apa èkúré e lé, won ò káwùsá
Pópóolá omo a yi gbigbi ló gbé won
Onílé oko, omo àrélu oba
Erúmosá, omo ateko tó ó mu bé wu lórí gbegbeegbe
Béè ló sí ti é gbèjè dànù lorà kan
Tétu taáyán tóde àyín
Erúmosá ta ni a wa, eniree ó mú pa
Eniire kò ó lóun ò ní jade,
Idà babà à mi kò lé won ò wàkò
E è bá mi sìpè fàdá kó wàkò
Eniire ni perí mórìn ìlú ò jísé.
Omo a jísé e re fóba .
Odérìnólá a,
Àkèó òdú, Adérin baba Dàda,
Ojúolápé Ajolóriwin
Olálomi, Agbéjà lójú olálomi
Omo a dugun nlá tó subu lawo
A-kí-ni, kò mòjàlà ìsègùn
Yèké ò ri yèké, yeke ni yeke
Yéké ò lépà ni pa oba
Òtòsì, nilé olúmòká nib o lùgìn è jéjé
Olálomí, olówó wa ni bo o le bi awo
Òòsà jé n tótá, n là lofà
Kí n fo ó luri awo yèrú ògbóbi
Nibi igi tó n sunyé kéte A bi i lófá , ó kiri, ó bìkàlò
Ìjàlò wón fayé lò wón, oláálomí
A ki i fowó leni a bi loaf kó dìnde
Láomí, omo oyege olú se.
A ti pe tòní, aadéolá
Àmòri òpó, baba ni n o máa pè ó
Bó dòla ò o
Adéolá, omo epééle e,
Omo iwù ló wu u jòkin
À ni ké e dúdu èlú
Omo a yoró làbú táso rè ò jòkin re
Omo a rówó olá mole,
Baba à mi lomo a ráwó-fà-ya-wòfà
Omo on ò létù lagbàlá, omo abaye
Ní won on sisé oko
À tip è ní tòrú o
Àmòri-ilá, àwon baba a ni n o máa pè o, bó dòla
Baba re ti gbéràlé abate
O mí máa helá a wà lérí
Baba yísá, ó gbo te pénpé té e deri arè
Baba a mi, erú n gbe áwà
Aténi gbò ò ni gbà á
Ládiípò, omo ògèdè, won ò yàgèn
À tì pè ni tònìí lónìi í o
Wón mú e sin ta pòlé o o,
À tólé àpá, omo jékó
Wón ò ni ke kari iba ìsàlè
Onílé láyinba ti jájó omo
Omo o ‘tago o rugi tèrù èkò
Oko ò mi, o muji teko abare fagbe leyìn
Omo a sole digbo, omo a sògbé dìgboro o
Olùúwa a mi, o sì yá a sààtàn dojà
Yóó so kèèké fidàní dìgbéjó
Omo a múnlé kangbó,
E ò rolúuwa a mi o
Òtá á lé yóò gboyè lábé
Adéolá kó somo gbogbo níbaníba
A à sì pè ni tònì í o
Báyìí, baba ní o máa pè ó bó dòlá
Adéolá, iba Ajolórínwin
A sí pè ní tònì í
Baba ni n ó máa pè o bó dòla o
Adéolá ìbá, a-jo-lorí-iwu
Omo opó ó ó.
Ládéjobi
Àhéjajùkú, À sì pè ni tònìí, ládéjobí
Ahéjàjúkú, Baba ní n o máa pè ó bó dòla
Ládéjobí, omo olówó tí I ni bí ose
Baba à mi ò bè mi owó rúrú, òpòtò mose ìwè
Ahe ni ó to o rì yè egbèje
Béè ni òfà won ònjò
Àhéke, àhèkè nílé àmòri to jège rèké
Ládéjobí,. Opa ile, opa oko
Ni i pa je.
Opa má pami je hain o lu
Opa má pamí je hain de júkú
Ládéjobí omo olówó ti i ru bi ose
Baba à mi obe mi owo riru òpòtò mose ìwè
Ahe to bí nìkú ibi abéré
Wón n yájú, wón n pera won lókinni
Ilé e re o jegbàá gbèje lo,
Níbi a gbé bi o lómo
Ajíbóròjí, ó jegbàá gbèje lo
Ajíjolá, ó jegbàá gbèje lo
Omo ekée re tó méku fóba
Baba a mi, òpò ò sì yá a tà kà
Ìyàwàrà,
Oko i jà lojà, larogún digbe nlé
Orogún digbé nlé mòóòko
Orogún digbe nlé mò ó òkété
Ajíjólá, omo ojú tí o gbélé jegbe oko
Òjé n wónyò, omo abéré won lókó
Owú ni ó ti ò jé kó o lókò obìnrin láyibi
Èwà okò tí o je o bomo olórò méjì gbélé
Awon ni bó ò bomo olórò méjì gbélé
Ajíjolá bi eni fomo óba lojúpo ló jo
O mo fomo omo lójúpo mò ón òpo
Ajíjola oya, sola gberú, o sola gbesin
Béè ló wòòyàn tàfà, ó foya gba lo gà
Elénté ni ó, béè lo ò yoko
Baba à mi, o sì yènà
Kò rook, ò yènè
O mo n kun fúya je mi òko
O nihin ti fáya je mò ó òkété
Ajíjolá omo ojú to o le genge sóko
Oje yoo ó omo àbèrè òko.