Asotito Aye
From Wikipedia
ASÒTÍTÓ AYÉ
Lílé: Asòtító Aye o, sóhun lòsìkà ìlú o
Ègbè: òsíkà ìlú o sóhun lasòtító ayé o
Lílé: Bíró mo bá pa ni, kí ni mo fi se yin ke wá so
Ègbè: Òdodo òrò tí o mí so, ìyan ló ń gún won lára
Lílé: Ayé ò fólódodo, èké lo kù ta ń bá kiri 5
Ègbè: Ìrìn tá jo ń rìn, ká mámà bára yodì
Lílé: Akánjú tulúorán
Ò bá jé na sùúrù si
Egbèje re kò tó í sebè
Ìràwò kò lè bósùpá tayò 10
Lílé: Mo mò
Ègbè: Ìrìn tá jo ń rìn
Ka má mà bára yodì
Lílé: Òré mi má a se mí
Kémi máa kí e 15
À ní ko ma se mí to bá fé
Kémi máa kí e
Ọro ò wò lojó tódò rú o
Ọlómo a mómó rè pamó ni
Ègbè: Ìrìn tá jo ń rìn 20
Ka má mà bára yodì
Lílé: Àwon ta fé léyín
Tan tun fe fi ge wa je
Àwon tí a dako fun
Tán fé fi dó wa láya 25
Awon ti a dáko fún
Tan tun fe fi dáya wa
Bóyá, ilè á da
Àjobí á da, ilè á da
Ègbè: Ìrìn tá jo ń rín 30
Ká má mà bára yodì
Lílé: Òré mi máa se mí
Kéma ma kí e
Òrò ò wò, lojó ó tódòrú o
Ọlómo á mómo re wole ni 35
Mo mò
Ègbè: Ìrìn tá jo ń rín
Ká má mà bára yodì