Congratulations
From Wikipedia
CONGRATULATIONS
Lílé: Ayé ń sátá pèlú Èsù ooo
Èké ni wón ń se lásan ni 185
Àtòrunbò -wa-sáyé
Ni mo ti múrawò mi bò o o yeyè
Èyin olùdènàà
E ma de mìí lonà
Éegbé awà 190
Ègbè: Orlando Owoh
Keenerííí
O kú oríire
Mo bá e dúpééé
Lílé: Àtíkékeré làjànàkú ti níyì jekùn lo 195
Láatòrun wááyé mo ti gbére tèmi jáde
Àtidádé kìnìún ko sèyín Olodùmaarè
Oba Èdùmàrè o o o
Ló fún wa ládé tiwaa
Àtòrun wáyé, 200
Mo ti múrawò mi bò o o yeye
Eyín olùdènàà
E ma de mìí lonà
Éegbé awà
Ègbè: Orlando Owoh 205
Keenerííí
O kú oríire
Mo bá e yòò
Mo bá e dúpééé
Lílé: Àtíkékeré làjànàkú 210
Láatòrun wááyé mo ti gbére tèmi jáde
Àtidádé kìnìún ko sèyín Olodùmaarè
Oba Èdùmàrè o o o
Ló fún wa lade tiwaa
Àtòrun wáyé, 215
Mo ti múrawò mi bò o o yeye
Eyín olùdènà o o
E má de míí lónà o
Yeyeyeee
Ègbè: Orlando Owòò
220
Keenérííí
O kú oríiree
Mo bá e yò o, mo bá e dúpééé
Lílé: Kò sónà te lè gbaa
Te lè fi táyé yìí lórùn ooo 225
Bo bá lógbón ko fi síkùn ara re ni
Orlando máa wò wón-an lóoyè
Kenerí sá ma wò wón-an lóye
A ń rín nilè, inú ń bélésin
À ń mumi tutu, olorí ń rojú 230
À ń sun búkà
Inú ń béni tó mí sunlé ooo
Orlando mi ooo,
Kíyèsarà re mo so
Ègbè: Orlando Owòò, Keenerííí 235
O kú oríire mo bá e yò
Mo bá e dúpééé
Lílé: Òrò pò ju òrò
Òrò. mà jura won
Òrò pò ju òrò 240
Òrò mà jura won
Adétè rí were ńse ló sa lùgbéé
Òrò maà jura won lo
Àrùn tó ń sòbo,
Kò tilè según rárá 245
Ìgún pá lórí,
Òbo pá ní fùrò o
Nítorí náà,
Sààsà ènìyàn ló ń féni dóóókàn
Orlando too bá lógbón 250
Fi síkùn arà re mo ti so
Yéyeyè
Ègbè: Sààsà ènìyàn ló ń feni dóóókàn
To bá lógbón, fi síkùn arà reee
Lílé: Ooko Funke Johnson, 255
Omo Ògúnléye o o
Baba Tósín o, kíyèsarà réé
Mo ti so
Ègbè: Sààsà ènìyàn ló ń féni dóókàn
To bá lógbón, fi síkùn arà reee. 260
Lílé: Bààbà Fùnmiláyò mi ooo
Bàbá Junior mi,
Omo Olówò madè ooo
Ègbè: Sààsà ènìyàn ló ń féni dóókàn
To bá lógbón, fi síkùn arà reee 265
Lílé: Ló ń féni dóóókàn
Ló ń féni dóóókàn
Ègbè: Sààsà ènìyàn ló ń féni dóókàn
To bá lógbón, fi síkùn arà reee