E ku iroju
From Wikipedia
E KÚ IROJU
E kú ìrójú omo Naijiria o 385
Rògbòdíyàn òrò ìyàn tí ń be nílè yìí o
E kú ìrójú o e
Isú ti di wíwón
Àgbàdo ò se é ra lòja
Gbogbo óunje awon omodé 390
Gbogbo è ló di wíwón repete
Láyé àtíjó o ó ò
Láyé àwon baba wa
Enikan láya méfà méjo
Síbèsíbè wón ń je séku dòla 395
Sùgbón láyé ìsèyín
Ení láya kan ò ma tún le bo
Bó bá jésè ló fa rú èyí o
Baba dárí jì wá o e
Èbè lá bèyìn ìjoba wa 400
Ebá wa rí sórò tí n be nílè yìí
Ká gbádúrà sólúwa
Kó ràwon asíwájú wa lówó
Tètè bá wa ri sórò tó wa nílè yìí o
Baba bá wà sé o è 405
Lílé: Òrìsà òkè tenu wón bàse
Ègbè: Òrìsà òkè tenu wón bàse
Lílé: Òrìsà òkè tenu wón bàse
Ègbè: Òrìsà òkè tenu wón bàse
Lílé: Tenu won bàse 410
Ègbè: Mòn mò tenu bàse
Lílé: Naijiria kóo ko rááyè
Kìgbà yìí tù wá ò
Ká rí je ká rí mu
Kógun má bé nílèe wa o 415
Òrìsà òkè tenu wón bàse
Baba wa ma jaye ye wa o
Mò jáyé dà wá o