Eran Ileya
From Wikipedia
ERAN ILÉYÁ
Lílé: E kú odún o
Gbogbo Onímòle
Ègbè: E tétí ke gbó mi 295
Mùsùlùmí òdodo
Lílé: Mo fé fenu ba dírè
Nípa òrò iléyá
Ègbè: E tétí ke gbó mi
Mùsùlùmí òdodo 300
Lílé: Eran iléyá te rí yen
Kì í seran pàsípààrò
Ègbè: E tétí ke gbó mi
Mùsùlùmí òdodo
Lílé: Ànábì Isíákà 305
Lo so ó deran pàsípààrò
Ègbè: E tétí ke gbó mi
Mùsùlùmí òdodo
Lílé: Àwon tí ò réran pa
Ló ye ko jeran iléyá 310
Ègbè: E tétí ke gbó mi
Mùsùlùmí ododo
Lílé: Eran iléyá te ri yen
Tomo aláíní gbogbo ni
Ègbè: E tétí ke gbó mi 315
Mùsùlùmí òdodo
Lílé: Gbogbo mùsùlùmí
Oba kó fún wón ni laádá
Ègbè: Báríká de sala
Mùsùlùmí òdoodo 320
Lílé: Ààwè kojá lo o
Iléyá wole o
Ègbè: Báríká de sala
Mùsùlùmí òdoodo
Lílé: Ààwè kojá lo o 325
Iléyá wole o
Ègbè: Báríká de sala
Mùsùlùmí òdoodo
Lílé: Aajì Adélù mi o
E kú odún o 330
Ègbè: Báríká de sala
Mùsùlùmí òdoodo
Lílé: Sàánúólú bàbá mi
E kú odún o
Ègbè: Báríká de sala 335
Mùsùlùmí òdoodo
Lílé: Rafiu Alálàbí
Aájì mi o daada
Ègbè: Báríká de sala
Mùsùlùmí òdodo 340
Lílé: Alálàbí Àláájì
Ràfíù mi o
Ègbè: Báríká de sala
Mùsùlùmí òdodo
Lílé: Aájí Alájè o 345
E kú odún o
Ègbè: Báríká de sala
Mùsùlùmí òdodo
Lílé: Vasco dàgamà
E kú odún o 350
Ègbè: Báríká de sala
Mùsùlùmí òdodo
Lílé: Làtí baba ‘Déwùmí ò
E kú odún o
Ègbè: Báríká de sala 355
Mùsùlùmí òdodo
Lílé: Bàbá Désígbìn
Deko menikan
Ègbè Báríká de sala
Mùsùlùmí òdodo 360
Lílé: Àsàlátù fónísé Olúwa
Ègbè: Àláwákúbárú
Lílé: E kú odun o
Ègbè: Ààsàlátù fónísé Olúwa
Lílé: Oba ko foríjin 365
Gbogbo òkú ìmòlè
Ègbè: Ààsàlátù fónísé Olúwa
Lílé: Lau lau kúbárú
Ègbè: Ààsàlátù fónísé Olúwa
Lílé: Bó wole Mékà, wole Mèdínà 370
Ègbè: Ààsàlátù fónísé Olúwa
Lílé: Odún odún yìí
Á dára fún wa o
Ègbè: Ààsàlátù fónísé Olúwa
Lílé: Bo wolá Nana Àwáwù 375
Ègbè: Ààsàlátù fónísé Olúwa
Lílé: Odùn odùn yìí
Á sán wá o
Ègbè: Ààsàlátù fónísé Olúwa
Lílé: Odún odún nìí 380
Á ye wá o
Ègbè: Ààsàlátù fónísé Olúwa
Lílé: Ààsàlátù fónísé Olúwa
Ègbè: Ààsàlátù fónísé Olúwa