Ile Yoruba
From Wikipedia
ILÈ YORÙBÁ
AKINOLA OLÁNREWAJU
Ìtàn Àkoólè Yorùbá
Gégé bí ìwádìí Àtàndá (1980), bí àwon Yorùbá se dé orílè-èdè Nàìjíríà àti àsìkò tí wón tèdó síbè kíi se ìbéèrè tí enikéni lè dáhùn ní pàtó nítorí pé àwon baba nlá won kò fi àkosílè ìse àti ìtàn won sílè gégé bí àjogúnbá.
Àwon ìtàn àtenudénu tí a gbó nípa ìsèdá yàtò sí ara won díèdíè. Ìtàn kan so fún wa pé àwon Yorùbá ti wà láti ìgbà ìwásè àti láti ìgbà ìsèdá ayé. Ìtàn òrùn pé kí ó wá sèdá ayé àti àwon ènìyàn inú rè. Ìtàn náà so fún wa pé Odùduwà sòkalè sí Ilé-Ifè láti òrun pèlú àwon emèwà rè. Wón sì se isé tí Olódùmarè rán won ní àsepé. Nípasè ìtàn yìí, a lè so pé Ilé-Ifè ní àwon Yorùbá ti sè, àti pàápàá gbogbo ènìyàn àgbáyé.
Ìtàn mìíràn tí a tún gbó so fún wa pé àwon Yorùbá wá Ilé-Ifè láti ilè Mékà lábé àkóso Odùduwà nígbà tí ìjà kan bé sílè ní ilè Arébíà léyìn tí èsìn Islam dé sáàrin àwon ènìyàn agbègbè náà. Àwon onímò kan nípa ìtàn ti ye ìtàn yìí wò fínnífínní, wón sì gbà wí pé bí ó tilè jé pé ó se é se kí àwon Yorùbá ní ìbásepò pèlú àwon ará Mékà àti agbègbè Arébíà mìíràn kí wón tó sí kúrò, ibi tí wón ti sè wá gan-an ni íjíbítì tàbí Núbíà. Àwon onímò yìí náà gbà pé Odùduwà ni ó jé olórí fún àwon ènìyàn yìí.
Kókó pàtàkì kan tí a rí dìmú ni pé Odùduwà ni olùdarí àwon ènìyàn tí ó wá láti tèdó sí Ilé-Ìfè gégé bí ìtàn méjéèjì tí a gbó se so. Tí a bá ye ìtàn méjéèjì wò, a ó rí i pé kò se é se kí Odùduwà méjèèjì jé enìkan náà nítorí pé àsìkò tàbí odún tí ó wà láàrin ìsèdá ayé àti àsìkò tí èsìn Islam dé jìnna púpò sí ara won. Nítorí ìdí èyí a lè gbà pé nínú ìtàn kejì ni Odùduwà ti kópa. Ìdí mìíràn tí a fi lè fara mó ìtàn kèjì ni pé léyìn àyèwò sí ìtàn ìsèdálè Yorùbá fínnífínní, ó hàn gbangba pé Odùduwà bá àwon èdá Olórun kan ní Ilé-Ifè nígbà tí ó dé ibè. Àwon ìtàn kan dárúko Àgbonmìrègún tí Odùduwà bá ní Ilé-Ifè. Èyí fihàn pé kìí se òfìfò ní ó ba Ilé-Ifè, bí kò se pé àwon kan wà níbè pèlú Àgbonmìrègún. Èyí sì tóka sí i pé a ti sèdá àwon ènìyàn kí òrò Odùduwà tó je yo, nítorí náà, kò lè jé Odùduwà yìí ni Olódùmarè rán wá láti sèdá ayé gégé bí a ti gbó o nínú ìtàn ìsèdá.
Lónà mìíràn èwè, a rí èrí nínú ìtàn pé Odùduwà níláti gbé ìjà ko àwon òwó ènìyàn kan tí ó bá ní Ilé-Ifè láti gba ilè, àti pàápáà láti jé olórí níbè. Ìtàn Móremí àjàsorò tí ó fi ètàn àti èmí omo rè okùnrin kan soso tí ó bí gba àwon ènìyàn rè sílè lówó ìmúnisìn àwon èyà Ùgbò lè jè èrí tí ó fìdí rè múlè pé Odùduwà àti àwon ènìyàn rè ja òpòlopò ogun kí wón tó le gba àkóso ilè náà lówó àwon òwó ènìyàn kan tí wón bá ní Ilé-Ifè gégé bí ìtàn àbáláyé ti so.
Orílè-Èdè Yorùbá
Ní orílè-èdè Nàìjíríà, àwon ènìyàn Yorùbá wà káàkiri ìpínlè bí i mésàn-án. Àwon ìpínlè náà ni Edó, Èkó, Èkìtí, Kogí, Kúwárà, Ògùn, Òndò, Òsun àti Òyó.
Lóde òní, Yorùbá wà káàkiri ilè àwon aláwò dúdú (Áfíríkà), Améríkà àti káàkiri àwon erékùsù tí ó yí òkun Àtìlántíìkì ká. Ní ilè aláwò dúdú. A le ríwon ní Nàìjíríà, Gáná, Orílè-Olómìnira Bènè, Tógò, Sàró àti béè béè lo. Ní ilè Améríkà àti àwon erékùsù káàkiri, a lè rí won ní jàmáíkà, Kúbà, Trínídáádì àti Tòbégò pèlú Bùràsíìlì àti béè béè lo.
Yàtò sí ètò ìjoba olósèlú àwarawa tí ó fi gómìnà je olórí ní ìpínlè kòòkan, a tún ní àwon oba aládé káàkiri àwon ìlú nlánlá tí ó wà ní ìpínlè kòòkan. Díè lára won ni Oba ìbíní, Oba Èkó, Èwí tí Adó-Èkìtì, Òbáró ti Òkéné, Aláké tí Abéòkúta, Dèji ti Àkúré, Olúbàdàn ti Ìbàdàn, Àtá-Ója ti Òsogbo, Sòún ti Ògbòmòsó ati Aláàfin ti Òyó.
Baálè ní tirè jé olórí ìlú kékeré tàbí abúlé. Ètò ni ó so wón di olórí ìlú kéréje nítorí pé Yorùbá gbàgbó pé ìlú kìí kéré kí wón má nìí àgbà tàbí olórí. Aláàfin ni a kókó gbó pé ó so àwon olórí báyìí di olóyè tí a mò sí baálè.
Lábé àwon olórí ìlú wònyí ni a tún ti rí àwon olóyè orísìírísìí tí wón ní isé tí wón ń se láàrín ìlú, egbé, tàbí ìjo (èsìn). Lára irú àwon oyè béè ni a ti rí oyè àjewò, oyè ogun, oyè àfidánilólá, oyè egbé, oyè èsìn àti oyè ti agboolé bíi Baálé, Ìyáálé, Akéwejè, Olórí omo-osú, Ìyá Èwe Améréyá, Mógàjí àti béè béè lo.
Èdè Yorùbá
Ní báyìí, tí a bá wo èdè Yorùbá, àwon onímò pín èdè náà sábé èyà Kwa nínú ebí èdè Niger-Congo. Wón tún fìdí rè múlè pé èyà Kwa yìí ló wópò jùlo ní síso, ní ìwò oòrùn aláwò dúdú fún egbeegbèrún odún. Àwon onímò èdè kan tilè ti fi ìdí òrò múlè pé láti orírun kan náà ni àwon èdè bí Yorùbá, Kru, Banle, Twi, Ga, Ewe, Fon, Edo, Nupe, Igbo, Idoma, Efik àti Ijaw ti bèrè sí yapa gégé èdè òtòòtò tó dúró láti bí egbèrún méta òdún séyìn.
Òkan pàtàkì lára àwon èdè orílè èdè Nàìjíríà ni èdè Yorùbá. Àwon ìpínlè tí a ti lè rí àwon tó n so èdè Yorùbá nílè Nàìjíríà norílè èdè Bìní. Tógò àti apá kan ní Gúúsù ilè Améríkà bí i Cuba, Brasil, Haiti, àti Trinidad. Ní gbogbo orílè-èdè tí a dárúko, yàtò sí orílè-èdè Nàìjíríà, òwò erú ni ó gbé àwon èyà Yorùbá dé ibè.
Àsà Yorùbá
Ìràn Yorùbá jé ìran tó ti ní àsà kí Òyìnbó tó mú àsà tiwon dé. Ètò ìsèlú àti ètò àwùjo won móyán lórí. Wón ní ìgbàtbó nínú Olórun àti òrìsà, ètò orò ajé won múnádóko.
Yorùbá ní ìlànà tí wón ń tèlé láti fi omo fóko tàbí gbé ìyàwó. Wón ní ìlànà tó so bí a se n somo lórúko àti irú orúko tí a le so omo torí pé ilé là á wò, kí a tó somo lórúko. Ìlànà àti ètò wà tí wón ń tèlé láti sin ara won tó papòdà. Oríìsírísìí ni ònà tí Yorùbá máa ń gbá láti ran won lówó, èyí sì ni à ń pè àsà ìràn-ara-eni-lówó. Àáró, ìgbé odún díde, ìsingbà tàbí oko olówó, Gbàmí-o-ràmí àti Èésú tàbí Èsúsú jé ònà ìràn-ara-eni-lówó.
Yorùbá jé ìran tó kónimóra. Gbogbo nnkan won sì ló létò. Gbogbo ìgbésí ayé won ló wà létòlétò, èyí ló mú kí àwùjo Yorùbá láyé ojóun jé àwùjo ìfòkànbalè, àlàáfíà àti ìtèsíwájú. Àwon àsà tó je mó ètò ìbágbépò láwùjo Yorùbá ní èkó-ilé, ètò-ìdílé, elégbéjegbé tàbí iròsírò. Èkó abínimó, àwòse, erémodé, ìsírò, ìkini, ìwà omolúàbí, èèwò, òwe Yorùbá, ìtàn àti àló jé èkó-ilé. Nínú ètò mòlébí lati rí Baálé, ìyáálé Ilé, Okùnrin Ilé, Obìnrin Ilé, Obàkan, Iyèkan, Erúbílé àti Àràbátan.
Orísìírísìí oúnje tó ń fún ni lókun, èyí tó ń seni lóore àti oúnje amúnidàgbà ni ìràn Odùduwà ní ní ìkáwó. Díè lára won ni iyán, okà, èko móínmóín àti gúgúrú.
ÌWÉ ÌTÓKASÍ
Adeoye, C.L. (1979): Àsà àti Ìse Yorùbá, Oxford University Press. Èka Èkó Èdè Yorùbá, Ilé-Èkó Gíga ti Àwon Olùkóni Àgbà tí ó jé ti Ìjoba Àpapò ní Osíèlè, Abéòkúta (2005): Ogbón Ìkóni, Ìwádìí àti Àsà Yorùbá.
Olatunji, O.O. (2005): History, Culture and Language, Published fro J.F. Odunjo Memorial Lecture, Series 5.
Opadotun Tunji ( ): Èkó Èdè Yorùbá Fún Ilé-Èkó Olùkóni Àgbà, Àkójopò Èkó Èdè Yorùbá.