Ilobuu
From Wikipedia
Ilobuu
1. Agbo ilé gbóbamú: Gégé bí itàn se so wón ni, àwon ìdílé yìí jé igbákejì oba, Iyen nip é ìdílè yìí náà le joba sùgbón kí Oba má baà pé méjì láàrin ìlú ni won se ni kí àwon jé gégé bíi ìgbá kejì Oba. Ìdí nìyí yí wón fi ń pè wón ní ilé Gbóbamú.
2. Agbo ilé Akéyán: Wón ní àwon ìdílé yìí fèrán láti máa je iyán púpò tóbè géè tó fi jé pé wón ti so ò dì orò láti máa gunyán ní àfèmójú fún ìyàwó tó bá sèsè wolé tàbí tí wón bá ń somo lórúko. Ìdí nìyí tí wón fi ń pè wón ní ilé akéyán.
3. Agbo ilé Jagun: Àwon ìdílè jagunjagun ní àwon ara ilé yìí. Ìdí nìyen tí wón fí ń pè wón ní jagun Olórò.
4. Agbo ilé Baara Olókùúa: Itan so pé òkúta ló wà ní àdúgbò yìí télè kí ó tó dí pé àwon kan kólé síbè, kódà àwon okuta kòòkàn sì wòn yíkà agbo ilé yìí títí di àsìkò yìí.
5. Agbo ilé Akín-in-nú: Akín-in-nú gbangba ló se e yan. Igbákeji Oba ni àwon ìdílé yìí, Ààyè púpò wà ní àjúde won tí ó fi ààyè sílè fún ènìyàn láti rìn bó se wù ú pèlú ìròrùn. Ìdí nìyen tí wón fi ń pè wón ní Akín-in nú gba se e yan.
6. Agbo ilé Alápata: Wón ní egúngún kan ní ilé yìí tó jé pé gbogbo ìgbà tí ó bá jáde ni ó máa ń gbé apata dání. Ìdí nìyen tí wón fi ń pè é ní ilé alápata
7. Agbo ilé Olú Òfin: Wón ní àwon ìdílé yìí ló máa ń pa kóríko fún esin Oba je.
8. Agbo ilé Àgànná : Orúko agbo ilé yìí. Ìyen bale Àgànná
9. Agbo ilé Ajítàpèé: Orúko eégún ìdílé yìí tí ó mòójó gaan ni wón fi so orúko ilé yií. Ìyen nip é tí egúngún yìí bá ti ń jó a máa tàpá sókè, á sì máa jó bíi òkòtó. O ní òsó bíi ìpépé lára.
10. Agbo ilé Òjáwúro: Wón féran láti máa ye ewúro ní ilé yìí tí ó fi jé pé ibe ni gbogbo àwon ará ìlú ti máa ń já ewúro fi se ègúsí.
11. Agbo ilé Ládòó: Wón ní àwon ìdílé yìí ní òògùn gidi gaan tí gbogbo ilé agbara won kìkì àdó ni wón fi kó sí ara ìlé náà. Ìdí nìyí tí wón fi ń pè wón ní ilé aládòó
12. Agbo ilé Amúnímòrun: Eégún kan wà ní ilé yìí tí ó le púpò tí ó jé pé tí ó bá jáde egba owo rè kò gbodò kan ènìyàn lárà, enikéni tí egba yìí bá kàn lára òrun lèrò rè. Ìdí abájo tí wón fi ń pè wón ní orúko yìí nìyí.
13. Agbo ilé Ògúnkéye: Olóògùn gidi ní àwon ìdílé yìí, Ológùn-ún ni wón. Won a sì máa kì wón báyìí “ata bíntín bojú jé”
14. Agbo ilé Afolú: Àwon ìdílé yìí féran láti máa fi olú je iyán.
15. Agbo ilé Ewé: Wón a máa gbin ewé èko ní ilé yìí ní ayé àtijó. Ìdí nìyen tí wón fi ń pè wón ní ilé onílé Ewé. (see Yoruba Place Names)