Ilu Aje-oruko-mo-Erin
From Wikipedia
Ilu Aje-oruko-mo-Erin
Erin-Ile
Erinmo
Erin-Osun
Erin-Ijesa
Erin-Oke
Boyede
O.M. Boyede
O. M. Bóyèdé (2005), ‘Àgbéyèwò Oríkì àwon ìlú Ajórúko-mó-Èrìn ní Ilè Yorùbá’., Àpilèko fún Oyè Eémeè, DALL, OAU, Ifè, Nigeria.
[edit] ÀSAMÒ
Isé yìí se àyèwò oríkì àwon ìlú Ajórúko-mó-Èrìn bí Èrìn bí Èrìnmò, Èrìn-Ìjèsà, Èrìn-Òkè, Èrìn-Ilé àti Èrìn-Òsun láàrin àwon Yorùbá apá Ìwò-Oòrùn Nàíjíríà. Bákan náà, isé yìí se àgbéyèwò orírun àwon ìlu wònyí, àjosepò tó wà láàrin ìsès àwùjo àti Ìbáratan won, pèlú ètò ìsèlú won. Ònà tí a gbà se ìwádìí yìí ni pé a gba ohun enu àwon oba ìlú wònyí, òpìtàn ní ààfin oba, àwon tó mò nípa oríkì ati àwon awo Ifá. A se àdàko àti ìtúpalè àwon ìfòròwánilénuwo àti oríkì tí a gbà sílè. Tíórì lítírésò ìbáraenigbépo àti ìfìwádìí-sòtumò ni a mú lò láti se àtúpalè àkóónú àti ìsowóloèdè nínú àwon oríkì yìí. Àwon ìwé tí ó wúlò fún isé yìí ni a yèwò ní àwon ilé ìkàwé. Àtúpalè isé yìí jé ká mò pé Ilé-Ifè ni orírun àwon ìlú Ajórúko-mo-Èrìn àti pé Èrìnmò ni wón koko tèdó sí kí àwon yòókù tó fónká lo sí ibi tí wón wà lónìí. Isé yìí tún fi hàn pé, bí ó tilè jé pé àwon ìlú Ajórúko-mó-Èrìn gba Ilé-Ifè gégé bí orírun won síbè, ìyàtò wà nínú èka-èdè, ètò ìsèlú àti odún ìbílè won. Bákan náà, o tún hàn nínú isé yìí oríkì jé kí a mo àwon àwòmó apààlà tí ó je mó àwùjo àwon ìlú Ajórúko-mó-Èrìn kòòkan àti àwon èèyàn won. Ní ìparí, isé yìí fihàn pé, bí ó tilè jé pé àwon ìlú wònyí fón káàkiri agbègbè Ìwò-Oòrùn Nàíjíríà nítorí ogun abélé Yorùbá, ìjà oyè, orò-ajé àti ìjà fún òmìnira ara eni, wón sI ní àjosepè tó fi wón hàn gégé bí òkan.
Alábòójútó: Dr. J.B. Agbaje
Ojú-Ìwé: 172