Ise-Ekiti
From Wikipedia
Ise-Ekiti
M.G. Fatoye
M.G. Fátóyè, (2003), ‘Àyèwò Fónolojì Èka Èdè Ìsè Èkìtì.’, Àpilèko fún Oyè Émeè, DALL, OAU, Ifè, Nigeria.
ÀSAMÒ
Isé yìí dá lórí àyèwò fonólójì èka-èdè Ìsè-Èkìtì, èyí tí ó jé òkan lára àwon èka-èdè tí à ń so ní ìpínlè Èkìtì. Láti se àgbékalè isé yìí, tíórì onídàró ni a lò. Ìpín mérin ni a pín isé yìí sí. Ní orí kìn-ín-ní ni a ti so ìtàn orírun Ìsè-Èkìtì. A so èrèdí isé yìí, ogbón ìwádìí tí a lò àti àyèwò isé tí ó wà nílè. Bákan náà, a so tíórì tí a lò fún isé yìí. Ní orí kejì ni a ti se àlàyé lórí àwon ìró inú èka-èdè ìsè-èdè Ìsè-Èkìtì. Bíi ìró kónsónántì, ìró fáwélì, ìró ohùn, isé ohùn, sílébù àti orísirísi. sílébù tí a lè rí nínú èka-èdè Ìsè-Èkìtì. Ní orí kéta àpilèko yìí ni a ti sàyèwo nípa ìgbésè fonólójì tí ó wà nínú èka-èdè Ìsè-Èkìtì. A wo ìpàróje, àrànmó àti ànkóò fáwélì. Ní orí kérin isé yìí ni a ti gbìyànjú láti wo àwon ìyàtò àti ìjora tí ó wà láàrin fonólóji èka-èdè Ìsè-Èkìtì àti ti olórí èka-èdè Yorùbá. Àgbálogbábò isé yìí dá lé àwon tuntun tí ó jáde nínú ìwádìí ti a se a si tóka sí àwon ibi tí a lérò pé isé kù sí.