Itan Aye Atijo
From Wikipedia
Itan Aye Atijo
Abioye Omowumi
ABIOYE OMOWUMI
ÀWON ÌTÀN AYÉ ÀTIJÓ
Ìtàn jé àwon òrò tàbí ìrírí tí àwon baba ńlá wa so tàbí ko sílè kí won ó tó fi ayé sílè. Òpòlopò ìtàn ayé àtijó ló jé àtenudénu nítorí pé ní àkókò tí won selé, kò tí ì sí mòn ón ko mòn ón ka. Òkan lára àwon ìtàn náà ni ìtàn on bi wón ti se te ilé-ifè dó. Gégé bí ìtàn àtenudénu tí mo gbó. Àjàlórun àti Agbonìrègún ni wón jìjo wà ní àjùlé òrun fún òpòlopò odun. Nínú òkùnkùn biribiri sì ni àwon méjèèjì wà. Ní ojo kan. Àgbonnìrègún so fún Àjàlórun pé òhun fé mo bí ó ti se rí. Àjàlórun so fún un wípé ó ní agbára láti pàw fún ohun kóhun, Àgbonnìrègún sì pàse pé kí ìmólè kí ó wà. Nígbà tí ìmólè dé, èrú ba Àgbonnìrègún nítorí pé ó rí ojú Àjàlórun tó béè tí ó fé kárò lórun fún Àjàlórun. Nígbà ti Àjàlórun fún un ní àyè láti wá sí ayé, Àgbonnìrègún rí i wí pé omi ni ó wà ni ibi gbogbo, èyí fún un ní ìdíwó láti se ohun tí ó fé se. Ó padà sí òdò o Àjàlórun ní òkè òrun. Ìgbà náà ni Àjàlórun tó rán Obàtálá wá sí ayé. Ó fún un ní ígbá, Alágemo, Àkùko Adìye, Eyìn, Èwòn ati Erùpè. Ní ojú ònà ìsatú òrun sí ìsálayé, Èsù tàn án je, ó fún un ní emu mu, ó sì sùn lo fon fon. Àkùko tí ó mú dání padà sí òrun, ìgbà náà ni Àjàlórun wa pe ìpàdé pé tani ó tún fé lo sí ayé. Gbogbo won ni wón pa lóló, ní ìgbèyìn, Àgbonnìrègún gbà láti lo te ilé ayé dó. Ó wá lótìtóó ó dà erùpè sílè léyìn ìgbà tí ó fi èwòn rò wá. Àkùkò tí ó mú dání sì bèrè sí tan erùpè náà ká. Ibi tí erùpè náà bat í ta sí á di ilè ti ó le. Báyìí ní ó té ilè. Gégè ìtàn náà se wí, Àgbonnìrègún nìkan kó ni ó dá wá sáyé, ni ìgbà tí ó ń bò, àwon òrìsà wá pèlúu rè. Itumò òrìsà ni àwon tí orí sà pò. Nígbà tí wón dá ayé, àwon òrìsà wònyí bèrè sí jayé bí ó ti wù wón. Èsè e won pò tó béè tí Àgbonnìrègún fi ké sí won, Ó bá won so òrò nípa Àjàlórun, ohun tí ó fi parí òrò o rè nip é, gé won mò pé, òrun ni ó mo eni tí yóò là. Ìdí nìyí tí wón fi yí orúko Àgbonnìrègún padà sí Òrúnmìlà. Àwon òrìsà wónyí ko yípadà kúrò nínú èsè e won Èyí ló mú kí “Orúnmìlà múra láti padà sí òrun nítorí pé èsè àwon òrìsà náà ti pò jù. Ní ìgbà tí ojó o títo rè é pé, àwon òrìsà ń sìn ín lo wón dé ìdí igi òpe kan, ibè ni òrúnmìlà ti sa èkùró mérìndínlógún, ó kó o fún àwon òrìsà náà. ó so fún won pé, ní ìgbà tí wón bá fé bá òhun sòrò, kí wón ba èkùró tí ó pè ni Ifá ní gbólóhùn. Èyí ni wón ń pè ní ìmò Ifá. Mole so wí pé kò sí ohun tí ó ń jé èsìn Ifá bí kò se Ìmò Ifá. Ìtàn yí fi agbára àti títóbi Olórun (Àjàlórun) hàn. Ìdí nìyí tí àwon ènìyàn fin í ìbèrù olórun. Olúkúlùkù ni ó ní ònà tí wón ń gbà sin Àjàlórun. Ìtàn náà tè síwájù pé, nígbà tí Àgbonnìrègún tí wón yí orúko rè padà sí Òrúnmìlà lo tán, àwon òrìsà wònyí túbò ń dá èsè mó èsè sí i ni. Lójó kan, wón so fún Àjàlórun wí pé, kí ó fi owó mú òrun kí àwon náà sì máa darí ayé. Àjàlórun rò wón títí sùgbón wón ní àwon náà fé dán agbára àwon wò. Ni Àjàlórun bá fi wón sílè, ní ìgbà tí á fi di ojó ìkejo, ilè ti gbe, ohun gbogbo tí wón gbin ti kú sí inú oko. Àwon odò kékèké ti gbe béè ni àwon odò ńlá ńlá pèlú. Ìyàn mú, kò sí omi béè ni kò sí ohun jíje, ìgbà náà ni àwon òrìsà náà tó padà sí òdò o Àjàlórun láti lo tuba. Léyìn èyí ni ohun gbogbo tó padà sí ipò. Ìtàn síso ní ayé àtijó wà fún ogbón kíkó àti òye