Litireso
From Wikipedia
Litireso
OHUN TÍ LÍTÍRÉSÒ JÉ
Eléyìí náà kò sàì ní orírun tirè láti inú èdè Látìn “LITERE” Èyí ni àwon géésì yá wo inú èdè won tí wón ń pè ni lete rature” Ìtumò tí a fún lítírésò máa ń yípadà láti òdò èyà ènìyàn kan sí èkejì láti ìgbà dé ìgbà. Lítírésò kò dúró sójú kan. Babalolá (1986), sàpèjúwe lítírésò pé:
“Àkójopò ìjìnlè òrò ní èdè kan tàbí òmíràn tó jásí ewì, ìtàn àló, ìyànjú, eré onítàn, ìròyìn àti eré akónilógbón lórí ìtàgé”
Tí a bá wo òde òní, ìtumò tí a fún lítírésò tún yàtò, fún àpeere a máa ń sàkíyèsí ìlò èdè tí wón fi ko ìwé kan yàtò sí èyí, a tún ka lítírésò kùn isé ònkòwé alátinúdá tàbí isé tó ní í se pèlú òrò ìlò ojú inú gégé bí ewì, ìtàn àròko àti eré oníse. A ó sì rí i pe awé tàbí èyà lítírésò tí a mènubà wònyí kó púpò nínú ìmò ìgbé èdá láwújo (folklore) mó ara, yálà, a ko, ó sílè, a rò ó so tàbí a se é léré yàtò fún àwon àkoó lè isé owó. Lítírésò tún jé irúfé àkoólè tó ní àbùdá èmí gígùn, ó máa ń fi ìsèse àti àsà àgbáríjo àwon èèyàn kan hàn. Àwon míràn tó tún sòrò lórí lítírésò ni àwon omo léyìn Mark: Àwon Marxist (1977) yìí gbà pé:
“Scrutiny of the literature could not be realize without the society”
Èyí ni pé:
“Lítírésò kò lè se é dá yèwò láìwo àwùjo tí a ko ó fún”
Kí ònkòwé kan tó lè se isé rè ní àseyanjú, irúfé onkòwé náà gbódò ni àtinúdá àtinúdá yìí pèlú ohun gan-an tí ó ń selè láwùjo ni yóò wá so di òkan nínú isé rè. Lara àwon tí ó sisé lórí ìlànà Marx yìí ni: Trosky ara Russia, Lucas àti Goldmann. Daviguand (1960) ni tíórì so pé
“Literature enumerate the future thought of an individual (Human being)
Èyí ni pé:
“Lítírésò wà fún láti máa so èrò okàn ènìyàn jáde nípa ojó iwájú”
Nípa yíye lítírésò wò, à ní láti wo èhun ìpìlè ìtumò, èyí ni wíwo gbogbo nnkan tí ó wà láwùjo yen olápapò láì dá òkan sí.