Oriki Sooko
From Wikipedia
Oriki Sooko
ÀGBÉYÈWÒ ALÁWÒMÓ LÍTÍRÉSÒ FÚN ORÍKÌ ÀWON SÒÓKÒ NÍ ILÈ IFÈ
SÀLÁMÌ Ejítóyòsí Oláyemí
A THESIS SUBMITTED IN PARTIAL FULFILMENT OF THE REQUIREMENT FOR THE DEGREE OF MASTER OF ARTS, DEPARTMENT OF AFRICAN LANGUAGES AND LITERATURES, OBÁFÉMI AWÓLÓWÒ UNIVERSITY, ILÉ-IFÈ. 2007
Contents |
[edit] ÀSAMÒ
Isé yìí se àgbéyèwò oríkì Sòókò, ó sì se àtúpalè ìlò-èdè inú oríkì náà. Èrèdí èyí ni láti se àlàyé kíkún nípa oyè Sòókò àti àwon àsà tí ó rò mó on ní ilè Ifè.
Ònà tí a gbà se ìwádìí yìí ni pé a gba ohùn enu àwon ìjòyè méta, àwon akígbe oba méta, Sòókò mérin láti ìdílé oba kòòkan ní Ilé-Ifè pèlú Sòókò ní Òkè-Igbó, Ìfétèdó, Ìpetumodù, Edúnàbòn àti Ifèwàrà. A se àdàko àti ìtúpalè àwon ìfòrò-wáni-lénu-wò àti oríkì tí a gbà nípa lílo tíórì ìbára-eni-gbé-pò àti tíórì ìfìwádìí-sòtumò èrò okàn, a se àmúlò àwon isé tó wà nílè lórí lítírésò àtenudénu Yorùbá pàápàá jù lo oríkì.
Isé yìí fi hàn pé oríkì Sòókò jé èrí tí ó kún ojú òsùwòn fún ìtenumó àwon àwòmò omo oba lókùnrin àti lóbìnrin ní ilè Ifè. Oríkì náà jé kí a mo pàtàkì ipò Sòókò gégé bí asojú àwon omo oba lókùnrin àti lóbìnrin nínú ètò ìsèlú ilè Ifè. Ènìyàn kò lè je Oòni (Oba Ifè) láìje oyè Sòókò tí í se òkan lára àwon ìgbésè tí a fi n je Oòni, sùgbón àwon Sòókò ní ìlú mìíràn yàtò sí Ilé-Ifè kò létòó láti je oba ìlú tí wón wà. Àkóónú oríkì náà se àfihàn agbára oògùn Sòókò, isé won gégé bí àgbè, afopo, alágbède, ode, jagunjagun, onísòwò àti èèwò won. Ní àfikún, ó jé kí á mò nípa àwon Sòókò gégé bí eni tí ó n soore, eni tí ó lawó, oníwà rere sí àlejò, arewà, olórò, onínú-fùfù, olórí-kunkun àti òfalè. Sòókò fara mó òfin ‘bádìye dàmí lóògùn nù, ma fó o léyìn’ tàbí òfin ‘oró tí ó dá mi ni mo dá o’. Oríkì won yìí ní àwon orin tí wón n ko mó on èyí tí ó dúró gégé bí ìsíde tàbí ìkádìí oríkì náà. Àdúrà wà nínú oríkì náà fún Sòókò tí à n kì. Èèwò ni fún Sòókò láti ko ilà ojú tàbí láti je olú ehè. Ìyàwó Sòókò tó sèsè bí omo kò gbódò je epo pupa tàbí iyò fún ojó méjo. Òpòlopò àwon odún ìbílè ìran Sòókò ló je mó ìrántí àwon ènìyàn tí a so di òrìsà nípa ohun ribiribi tí wón ti gbé se ní ìgbà ayé won. Onà èdè tí ó hànde jù nínú oríkì Sòókò ni àwítúnwí, àwítúnwí kónsónàntì àti fáwélì, ìfohùngbohùn, ìyánròfééré, àfiwé tààrà, àfiwé elélòó, ìsohundèèyàn àti ìbádógba. Isé yìí wá gbà pé oríkì Sòókò se pàtàkì nípa pé ó se àfihàn òpòlopò ohun tó je mó ètò ìsèlú, àsà àti ìse ní ilè Ifè.
Name of Supervisor: Dr. (Mrs) J. O. Sheba
Number of Pages: xvi, 217
[edit] ABSTRACT
The study appraised Sòókò’s praise poetry (oríkì) and analysed the stylistic devices used in the poetry. This was with a view to elucidating the chieftaincy title of Sòókò and the traditions associated with it in Ifè land.
The research methodology employed included oral interview with three traditional chiefs, three palace singers, four selected Sòókò in each of the four ruling houses in Ilé-Ifè and two Sòókò from each of the other towns concerned; that is, Òkè-Igbó, Ifètèdó, Ìpetumodù, Edúnàbòn and Ifèwàrà. The data collected were transcribed and analysed, using sociological and hermeneutical theories of literature. Critical works on Yorùbá oral literature, especially oríkì were consulted.
The result showed that Sòókò’s praise poetry was rich in the affirmation of attributes of princes and princesses in Ifè land. The poetry revealed the important position of Sòókò as the representatives of princes and princesses in the political administration of Ifè land. Nobody could be crowned Oòni (the Ifè king) without first undergoing the installation rites of a Sòókò. However, Sòókò in towns other than Ilé-Ifè had no right to kingship. The content of the poetry also revealed the spiritual prowess of Sòókò; their occupations as farmers, palm oil producers, blacksmiths, hunters, warriors, traders, and their taboos. In addition, it highlighted Sòókò’s benevolence, generosity, hospitableness, grandeur, opulence, aggressiveness, stubbornness and concupiscence. Sòókò kept the law of reciprocity, or, of an eye-for-an-eye. Their praise poetry was accompanied by songs, which could serve as a prologue and as an epilogue to the performance of the poetry. The song could contain prayers for the particular Sòókò being eulogized. It was taboo for Sòókò to bear facial marks or eat a type of mushroom called ehè. Wives of Sòókò who had just given birth must not eat palm-oil and salt for eight days, most of the traditional festivals in Sòókò families had to do with deities and were performed in remembrance of heroic ancestors. Prominent among the stylistic devices used in Sòókò’s panegyric poetry were repetition, alliteration and assonance, tonal counterpoint, allusion, simile, metaphor, personification and parallelism.
The study concluded that Sòókò’s praise poetry was very important in that it revealed a great deal about political administration and cultural practices in Ife land.
Name of Supervisor: Dr. (Mrs) J. O. Sheba
Number of Pages: xvi, 217
[edit] ÌFÁÁRÀ
Oríkì Sòókò ni a fé se àtúpalè tó jinlè lé lórí nínú àpilekò yìí. Tí kò bá ní ìdí, obìnrin kì í jé Kúmólú. Ìdí abájo tí mo fi yan orí òrò yìí ni wí pé mo se àkíyèsí pé tí àlejò kan bá wo Ilé-Ifè tàbí òkan lára àwon ilú tó wà lórí ilè Ifè lónìí, esèkesè ni yóò máa gbó tí àwon ará ìlú tàbí àwon àlejò mìíràn pàápàá yóò ma dárúko Sòókò níwá àti léyìn. Dídárúko Sòókò yìí lè jé nípa kíkí won tàbí kíkì wón tàbí fifi orúko tàbí oríkì yìí dá àpárá pé “Nlé o Sòókò”. Èyí yòó fé kí irú àlejò béè fé topinpin ìdí tí Sòókò yìí fi gbayì béè.
A lè rí Sòókò gége bí èdá kan béè si ni a tún le rí i gégé bí oyè tí ènìyàn ń je tàbí kí a rí i gégé bí oríkì tí a fi ń ki ènìyàn. Wonúwòde ni oríkì Sòókò ní ilè Ifè. Àwon oríkì kan wà tó pa gbogbo Sòókò ilè Ifè po, àwon oríkì kan sì wà tó jé pé enu àwon agboolé tí ó wà ní ìdílé oba kan náà ni a lè fi wón kì. Àwon kan gbà pé òkan soso ni oríkì Sòókò ní ilè Ifè. Eyí rí béè nítórí pé abé agbòòrùn kan náà tí í se omo oba ni wón wà. Ìdí mìíràn tí a tún fi lè gbà pé òkan náà ni wón ni àlàyé tí a se pé oríkì kan wà tó pa gbogbo won pò
Oko kì í jé ti baba tomo kó má ni ààlà, ìyàtò díè díè wà nínú àwon oríkì Sòókò wònyí. Èyí ni pé tí a bá ń ki oríkì náà bò, tí ó bá dé ààyè kan oríkì náà yóò máa yà sí ti agboolé kòòkan. Ohun tó fi ìdí èyí múlè ni ìyàtò tó wà nínú orúko agboolé tí a ń pe Sòókò kòòkan mó.
Òpòlopò isé ni àwon ènìyàn ti se lórí oríkì ní ilè Yorùbá. Irú àwon isé béè ni; Odùbítàn (1961), Adétóyèse (1963), Atiládé (1963), Babalolá (1967), Barber (1979), Adéoyè (1982), Akínyemí (1991), Àjàyí (1995), Ológunlékòó (1998). A wá rí i pé àwon isé lórí oríkì wònyí dá lórí Yorùbá Òyó àti Èkìtì, èyí tí ó túmò sí pé kò sí isé lórí oríkì Sòókò ní ilè Ifè. Ohun tí a lérò pé ó lè fa èyí ni pé èyà Yorùbá Òyò àti Èkìtì pò ju èyà Ifè lo. Èyí tí o sì lè mú kí àwon òmòràn má tètè ko ibi ara sí i. Ibi tí a sì lérò pé won kò ko ibi ara sí yìí ni àpilèko yìí fé gbé yèwò.
Ohun àrídájú wa ni pé gbogbo àgbáyé ni a ti mò pé àwùjo máa ń yí padà. Bí àwùjo se ń yi ni lítírésò rè ń bá a yí tí ó sì ń gbé ohun gbogbo nípa àwùjo náà sita fún aráyé rí. Ìdí nìyí tí isé yìí tóka sí ìgbé ayé àwon Sòókò ní ilè Ifè láyé àtijó àti láyé òde-òní gégé bó se hàn nínú oríkì won. Ó tóka sí Sòókò láàrin àwon ènìyàn rè gégé bí ìpìlè ìtàn àti ètò ìsèlú Ilé-Ifè.
[edit] Èrèdí Isé
Àkíyèsí wa nípa Sòókò gégé bí asojú àwon omo oba lókùnrin àti lóbìnrin, tí oríkì won sì hànde ní ilè Ifè, ló mú kí a fé láti se àtúpalè oríkì won ní kíkún.
Nípa àtúpalè oríkì yìí, a lérò pé a ó ní ìmò tó jinlè nípa ipò àti ojúse àwon Sòókò ní ilè Ifè. Bákan náà ni a ó ní ìmò tó gbòòrò nípa ohun gbogbo tó rò mó àwon Sòókò ní ilè Ifè gégé bí oríkì won se fi han.
[edit] Èròngbà Isé
Èròngbà wa ni láti tan ìmólè sí ohun tí Sòókò jé ní ilè Ifè, láti se àkójopò oríkì rè. Ìwádìí yìí yóò topinpin ohun tó bí Sòókò ní Ilé-Ifè àti pàtàkì rè nínú ètò ìsèlú àti ètò oba jíje ní Ilé-Ifè
Ìwádìí yìí jé kí a mo ìjora àti àwon àwòmó apààlà nínú oyè àti oríkì Sòókò ní Ilé-Ifè àti àwon ìlú mìíràn tí Sòókò wà ní ilè Ifè.
A gbìyànjú láti se àtúpalè àkóónú oríkì náà àti ìlò èdè inú rè.
Àbáyorí isé yìí jé àfikún isé ìwádìí lórí oríkì orílè ilè Yorùbá, ó sì tún jé kí a mò dájú pé a lè fi oríkì wádìí ipò, ìrísí, ìhùwàsí, isé, èèwò, odún àti orin àwon Sòókò ní ilè-Ifè
[edit] Ònà Ìgbàsèwádìí
Ogbón ìsèwádìí yìí pin sí ònà méta. Ònà kìíní dá lé àwon ìgbésè tí a fi kó àwon oríkì Sòókò àti àwon ohun mìíràn tí ó je mó isé yìí jo. Ònà kejì je mó ogbón tí a fi ko àwon oríkì tí a gbà sílè. Ònà keta si je mo àwon àkoólè tí a kà láti mú kí isé náà kése járí.
Ìgbésè méjì ni a lò láti kó àwon oríkì Sòókò àti àwon ohun mìíràn tí ó je mó isé yìí jo. Àkókó ni pé a se àwárí àwon abénà-ìmò mérìndínlógbòn. Lára àwon abénà-ìmò náà ni àwon ìjòyè láàfin, àwon akéwì, àwon ìsòrò ìbo àti díè lára àwon Sòókò àwon ìdílé tí a lò. Àwon abénà-ìmò tí a lò yìí jé ti Ilé-Ifè àti àwon ìlú mìíràn ní ilè Ifè tí isé yìí je mó. Àwon ìlú náà ni Òkè-Igbó, Ìfétèdó, Ìpetumodù, Edúnàbòn àti Ifèwàrà. Ìgbésè kejì ni a ti gba oríkì àwon Sòókò pèlú àwon ohun mìíràn tí ó je mo isé yìí latí enu àwon abénà-ìmò sí orí fónrán tí a sì se àdàko rè sí inú ìwé.
Ní ònà kejì, a ko oríkì Sòókò ìdílé kòòkan ní Ilé-Ifè àti oríkì Sòókò àwon ìlú mìíràn ní ilè Ifè sí abé ìsòrí òtòòtò kí ó lè rorùn fún wa láti se àfiwé won. Àwon ìdílé Sòókò ní Ilé-Ifè tí a ko oríkì won náà ni Ògboòrú, Láfogído, Gíèsí àti Osìnkólá, a sì ko ti àwon ìlú tí ó kù náà.
Ònà keta je mó lílo sí ilé-ìkàwé láti ka òkan-ò-jòkan ìwé tí ó lè ràn wá lówó fún àtúpalè isé náà.
[edit] Ibi tí agbára isé yìí mo
Àgbéyèwò aláwòmó-lítírésò fún oríkì àwon Sòókò ní ilè Ifè ni isé yìí dá lé, pàtàkì sì ni oríkì jé nínú lítírésò alohùn Yorùbá. Fún ìdí èyí, isé yìí kò kojá oríkì àwon Sòókò ní ilè Ifè. Àwon ìlú tí a ń tóka sí náà ni Ilé-Ifè, Òkè-Igbó, Ìfétèdó, Ìpetumodù, Edúnàbòn àti Ifèwàrà. Bí ó tilè jé pé Ìpetumodù àti Edúnàbòn jé èyà Yorùbá Òyó, a o se àlàyé bí Sòókò se dé àwon ìlú náà nígbà tí a bá ń se àlàyé nípa bí Sòókò se dé àwon ìlú ní ilè Ifè.
Gégé bí ìgbàgbó àwon Sòókò pé Ilé-Ifè ni oyè náà ti dé àwon ìlú tí won wà àti pé nínú ètò ìsèlú Ilé-Ifè ni wón ti se pàtàkì, kò ní pon dandan láti se àlàyé ètò ìsèlú àwon ìlú mìíran tí Sòókò wà, sùgbón a se àlàyé ètò ìsèlú Ilé-Ifè tí wón ti se pàtàkì.
[edit] Tíórì Àmúlò
Tíórì ni ogbón tàbí ònà tí a fi ń se àlàyé nnkan tàbí tí a fi ń se nnkan. Èwè, a tún lè pe tíórì ní òye tàbí ìlànà kan gbòógì tí a ń tè lé láti fi se ohun kan tàbí láti fi yiiri nnkan.
Léyìn tí a se àyèwò isé yìí, a rí i pé ó je mó àwùjo kan, ó sì je mó kí a lo máa topinpin àwon nnkan tàbí ònà tí ó je mó àkóónú oríkì náà. Nígbà tí àwon ènìyàn bá wà ní àwùjo kan, dandan ni kí won sùwàdà. Ìsùwàdà won yìí ni yóò mú ìlosíwájú bá àwon ènìyàn àwùjo náà lápapò. Èso àwùjo ni oríkì jé. Ó tún je mó kí ènìyàn ní ìmò èdè tí a fi so àsoyé nípa àsà àwùjo náà. Eyí ni ó mú wa pinnu láti lo tíórì ìbára-eni-gbé-pò àti tíórì ìfìwádìí-sòtumò èrò okàn láti se àtúpalè oríkì Sòókò ní ilè Ifè.