Erin
From Wikipedia
Erin
O.M. Boyede
O. M. Bóyèdé (2005), ‘Àgbéyèwò Oríkì àwon ìlú Ajórúko-mó-Èrìn ní Ilè Yorùbá’., Àpilèko fún Oyè Eémeè, DALL, OAU, Ifè, Nigeria.
ÀSAMÒ
Isé yìí se àyèwò oríkì àwon ìlú Ajórúkomó Èrìn bí Èrìn bí Èrìnmò, Èrìn-Ìjèsà, Èrìn-Òkè, Èrìn-Ilé àti Èrìn-Òsun láàrin àwon Yorùbá apá Ìwò-Oòrùn Nàíjíríà. Bákan náà, isé yìí se àgbéyèwò orírun àwon ìlu wònyí, àjosepò tó wà láàrin ìsèsi àwùjo àti Ìbáratan won, pèlú ètò ìsèlú won.
Ònà tí a gbà se ìwádìí yìí ni pé a gba ohun énu àwon oba ìlú wònyí, òpìtàn ní ààfin oba, àwon tó mò nípa oríkì ati àwon awo Ifá. A se àdàko àti ìtúpalè àwon ìfòròwánilénuwo àti oríkì tí a gbà sílè. Tíórì lítírésò ìbáraenigbépo àti ìfìwádìísòtumò ni a mú lò láti se àtúpalè àkóónú àti ìsowóloèdè nínú àwon oríkì yìí. Àwon ìwé tí ó wúlò fún isé yìí ni a yèwò ní àwon ilé ìkàwé.
Àtúpalè isé yìí jé ká mò pé Ilé-Ifè ni orírun àwon ìlú Ajórúkomo Èrìn àti pé Èrìnmò ni wón kọkọ tèdó sí kí àwon yòókù tó fónká lo sí ibi tí wón wà lónìí. Isé yìí tún fi hàn pé, bí ó tilè jé pé àwon ìlú AjórúkomóÈrìn gba Ilé-Ifè gégé bí orírun won síbè, ìyàtò wà nínú èka-èdè, ètò ìsèlú àti odún ìbílè won. Bákan náà, o tún hàn nínú isé yìí oríkì jé kí a mo àwon àwòmó apààlà tí ó je mó àwùjo àwon ìlú AjórúkomóÈrìn kò òkan àti àwon èèyàn won.
Ní ìparí, isé yìí fihàn pé, bí ó tilè jé pé àwon ìlú wònyí fón káàkiri agbègbè Ìwò-Oòrùn Nàíjíríà nítorí ogun abélé Yorùbá, ìjà oyè, oròajé àti ìjà fún òmìnira ara eni, wón sI ní àjosepè tó fi wón hàn gégé bí òkan.
Alábòójútó: Dr. J.B. Agbaje
Ojú-Ìwé: 172