Nọ́mbà
From Wikipedia
Nomba je ohun afoyemo to duro fun iye tabi iwon. Ami-isoju fun nomba ni an pe ni aminomba (numeral). Ni ede ojojumo, a n lo awon aminomba bi akole (fun apere nomba telifonu, nomba ile). Ninu imo isiro itumo nomba ti s'akomo awon nomba afoyemo bi ida (fraction), alapaosi (negative), tikonionka (transcendental) ati nomba tosoro (complex).
Awon ona isesiro nomba bi aropo, iyokuro, isodipupo, ati isepinpin ni a n sewadi won ninu eka imo isiro ti a mo si aljebra afoyemo (abstract algebra), nibiti a ti n sewadi awon ona nomba afoyemo bi egbe (group), oruka (ring) ati papa (field).